Kristi ninu wa, ireti ogo

Kristi ninu wa, ireti ogo

Text: Koll 1:27, Rm 8:10-11

Oro Akoso: Ti a ban se idupe pe Kristi oluwa ji dide kuro ninu oku, ohun ayo, lati inu irohin ayo ti o ye ki a ma se ni, pe gbogbo ipa ti iku lo, gbogbo erongba buburu satani lati di eto olorun lowo di asan.

Ipile (foundation) ti o lagbara ati opo ti igbagbo awa kristieni duro le lori ni Ajinde Kristi kuro ninu oku. Ajinde Kristi ni opolopo itumo ti o se iyebiye si awa onigbagbo kristieni. Bi iku re se se Pataki naa ni ajinde re pelu. Ise igbala wa, irapada wa ti o wa se ko pe, bi ko ba si ajinde re. Bi Kristi ko ba jinde igbagbo wa yio je etan, tabi duro lori iro, nitori awon asotele re. Sibe opo ninu aye ni won ko gba isele yi gbo titi di oni, edun okan ni eyi je nitori wipe isina won le yori si egbe ayeraye.

Awon ohun ti a ko lee sai kiyesi ninu eko yi:

 1. Okunfa iwasaye Jesu Kristi
 2. Ikure re, Isinku re, ati ohun ti iku re se fun wa: Bo ti wa ku, ti ko ba jinde, kop e, ko ni itumo.
 3. Awon isele ti o ro mo ajinde re
 4. Awon ero ori (theory), awon onimo, tabi eniyan ti won ko gbagbo nipa ajinde
 5. Die ninu awon eri ajinde Jesu Kristi
 6. Ise Pataki ajinde re fun awa onigbagbo.

Okunfa Iwa saye Kristi: Iwasaye Kristi, ijiya ati iku re, je nitori isubu eniyan (ese iran eniyan) RM 5:12,17, Gen 2:16-17, 3: 1-13, 14-19, 22-24. Aigboran, ese, isubu eniyan yi mu;

 1. ki o padanu ogo olorun, aworan olorun, isejoba tabi isakoso lori eda alaye ati aye, o fa iku tie mi. Isakoso eniyan ati aye bo sabe satani, eniyan di eru ese ati satani, dipo ki o maa se ife olorun, kiki ibi ni o yipada si ni sise, nipa bee eniyan wa labe ibinu olorun, eyiti yi o yori si iparun ati egbe gbogbo eniyan iba ma sii ti Jesu ti o wa si aye; Gbogbo iran eniyan ni o wa labe ibinu yi. Idi ti Kristi fi wa fun ise igbala niyi.

Nigbati Kristi wa si aye fun ise igbala eniyan yi (bi Adamu keji) Onirunru ona ni satani gba lati dii lowo ise nla yi, sugbon nipase iranlowo Emi mimo olorun, o lee se aseyori. Satan ife gba ona kanna eyiti o gba segun Adamu akoko lati mu un, lati fii sinu igbekun. Matt 4: 3-11, LK 4:4-6. Kinni asiri isegun Kristi? Oro olorun ati emi olorun ti n gbe inu re ni. Oro naa je fitila ati imole ni oju ona awa onigbagbo pelu.

Iku re ati ohun ti iku re se fun wa:

 1. O se etutu fun ese wa lati yi ibinu olorun pada. 1Jn 2:2
 2. O se ilaja laarin awa ati olorun. RM 5:8,-10
 3. Nipa iku etutu re, a ri idarijin ese wa gba. !Jn 2:1-2
 4. Nipa iku etutu re ni a je eni itewogba lodo olorun. II Kor 5:21
 5. O mu isota ti a wa laarin awa ati olorun kuro. II Kor 5:18
 6. Nipa etutu eje Kristi a di eni irapada, ominira kuro lowo satani ati ijegaba re.
 7. Iku etutu re ni o gba wa lowo iku ayeraye. Jn 3:16
 8. O gba wa lowo ebo riru gbogbo igba. Heb 10: 16-17
 9. O gba wa lowo egun ofin ati aisan. Matt 8:17, Gal 3:13.

Awo isele ti o rom o ajinde re:

 1. Saaju ki o to ku ni o ti so asotele nipa iku at ajinde re. sugbon oye ohun ti o nso ko ye won. Matt 16:21-23, Mk 8:31-33, 9:31-32, LK 18:31-34, Jn 11:21-27
 2. Josefu ara Arematia ni o to awon igbimo lo lati toro oku Jesu Kristi. Matt 28:57-61.
 3. Ninu akosile Mathewu ni a ti ri bi isele nla naa ti ri. Matt 28:1-4
 4. Aimoye awon omo ehin Kristi ko je ki won o ni irun imurasile ti o ye. LK 24:1-8
 5. Akitiyan awon olori elesin, ni fifi edidi di enu ona iboji ninu eor ati di eto olorun lowow ja si pabo. Matt 27:62-68.

Awon Ero Ori (theories) awon onimo kan, eyiti o lodi si otito ajinde Kristi:

 1. Awon kan so wipe itanje ni oro ajinde Kristi (fraud theory), won gba wipe etan ti won moomo gbe le awon eniyan lori ni. Sugbon eyi ko ba iwe mimo mu.
 2. Swoon Theory: Ero ori eyi so wipe Jesu daku ni, pe awon omo ogun ko pa a rara, wipe itura iboji ati awon turari oloorun didu ni o mu ki o jinde si aye pada. Eyi pelu lodi si otito iwe mimo
 3. The Hallucination theory: Won so ninu eor ori won wipe awon apsteli nfe lati ri Jesu, won si nro ninu okan won wipe yio ji, nitorina ni iwoye, ironu won ni won ti rii wipe o jinde.
 4. The Ghost theory: Ero ori awon miran ni wipe (Ghost) iwin re ni won ri, ti won sebi ohun ni. Sugbon lodi si eyi, LK 24:39,43; Jesu, leyin ajinde re, ni ara ti o se gbamu, ti o si see fi owo kan.
 5. The Myth Theory: Awon elero odi wonyi so wipe itanju ti kii sooto ti o ti wa lati igbaani ti awon ara igbaani fi le awon eniyan lowo ni, sugbon gbogbo Bibeli ni o lodi si eyi.

Die ninu awon eri ajinde jesu Kristi:

 1. Iboki ti o sofo. Matt 28:6, LK 24:3
 2. Eri awon angeli. Matt 28:6, LK 24: 5-6
 3. Awon eniyan ti won baa soro leyin ajinde re; Peteru, Maria, Cleopas, Thomas.
 4. Jesu je, o si tun mu pelu awon omo ehin re lehin ajinde.
 5. Awon ti o le ni Eedegbeta rii, lehin ajinde re. I Cor 15:6
 6. O fi ara ha stephanu Ajeriiku, ni igba iku re. Acts 7:56.
 7. O fi ara han Paul ni ona Damascus. Acts 9:5

Bi o ti se Jinde

 1. Nipa agbara olorun Baba. Acts 2:23-24
 2. Nipa Agbara Kristi funra re. Jn 2:19, 10:17-18
 3. Nipa agbara emi mimo. I Pet. 3:18, Rm 1:4.

Ise Pataki Ajinde Jesu Kristi fun awa Onigbagbo:

 1. Ajinde Jesu Kristi n fu jije omo olorun re ni tooto han wa, o fi jije omo olorun re han nipa imuse asotele re, wipe ohun yio ku, ohun yio si jinde. Rm 1:3-4. Wipe jiji ti o jinde kuro ni ipo oku je eri wipe o je omo olorun.
 2. Ajinde Jesu Kristi je amin idaniloju wipe Jesu ni agbara ati ase lati ja ide ses, lati segun iku, iboji, isa oku ati Satani. Nipa isegun ori igi agbelebu ati ti iboji, o ti ni agbara lati tu iran eniyan sile kuro ninu igbekun ese ati iku. Iru agbara kanna ti o ji Kristi dide kuro ninu oku, naa ni onigbagbo nrii gba nigba ti o ba jewo Kristi ni oluwa, lati bo lowo ese, yi o se ise iyipada ti inu, ti yio si ma gbe igbe aye otun eyiti npa ese run. RM 8:11, 6:14. Nitori a ti fun wa ni emi mimo ati agbara ajinde. Agbara yi ni o nran awon onigbagbo kristieni lowo lati bori awon ese ati satani, lati gbe igbe aye iwa mimo. Phil 2:13, 4:14/ Bi ko ba si ti emi mimo olorun ati oro olorun ninu wa, ife ota I ba se le wa lori.
 3. Ajinde Kristi n soo di mimo fun aye wipe olorun alaaye ni o n sakoso ijoba olorun ti awa onigbagbo kristienin, kii se olorun oku. Igbagbo kristieni nikan ni orison idasile re wa laaye. Buddha, Brahma (Hinduism), Mohammed (Islam), won ku, won ko jinde, oku won wa ninu is alai mo ohun ti opin won yi o je. Sugbon Kristi ku o si jinde ni ibamu pelu oro re. Rev 1:17-18.
 4. Ajinde Jesu Kristi je idaniloju fun awa omo ehin re wipe a ni ireti ajinde si iye ainipekun lehin iku. I Kor 15:16-18, 51-58, 20, 23, I Tess 4:14. Idi niyi ti a fi pe Kristi ni akobi ninu awon oku. I kor 15:20-23. Eyi n fihan wipe ojo nbo, akoko nbo ti a o bo kuro ninu laala ati iponju inu aye ese yi. A o ji wad ide bi a ba ti ku. A o si pa wa larada bi a ba wa laaye fun igbasoke. Oye yi ti o ye awon omo ehin isaaju ni o ran won lowo lati fi ara da gbogbo wahala, inunibini ati iponju akoko ti won. I cor 15:16-18,30.
 5. Ajinde Kristi nso niti eri idaniloju idajo ti o nbo wa. Acts 17:30. Ajinde Jesu Kristi nfi han pe Jesu Kristi je omo olorun ni tooto ati onidajo ti o gajulo, eniti eni kookan yio farahan niwaju re ni opin aye. Nipase re ni a o se idajo aye ati oku.

Ireti Kristi Ti o ku fun wa lori wa:

 1. Ki a gba a gegebi oluwa ati olugbala wa, ki a fi igbagbo wa si inu ise igbala re. Jn 1:11-12
 2. Ki a fi aye gbaa ninu okan wa, ki a yonda okan wa fun un. Owe 23:26, Rev 3:20. Fifi aye gba oro re, emi re fun iyipada igbe aye. Kristi ninu eni kookan ni ireti ogo. Koll 1:25-27, Rm 8:10-11. Nje eniyan to ni Jesu le wa ni enu eniyan, ninu iwoso re, orin re, ki o ma si si ninu okan re? Ezekiel 33:31-33, Matt 7:21-23, Matt 15:8. Bi eniyan ba je iru eni bayi niwaju olorun, kinni yio je opin re ni ojo idajo.
 3. Gbigbe igbe aye wa fun Jesu Kristi. II Kor 5:15, Gal 2:19. Rm 6:11,13. Apere Paul; apaniyan nigbakan ri.
 4. Titan irohin rere naa kale fun gbogbo eda. LK 24: 44-49, Matt 28:18.
Share

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *